Adarí ilé -isẹ́ ikọ̀ ọmọ -ogun orílẹ̀ èdè Nàíjírìà sàbẹ̀wò si ibi ìgbáradì ìgbanísíṣẹ́, ní Ibùdó Falgore
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ní ìtèsíwájú lórí ìrìn -àjo rẹ̀, adari ile-isẹ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria ọgagun Faruk Yahaya, ṣàbẹ̀wò ti se abẹwo sí ibùdó ìgbaradi awọn ọmọ ogun orilẹ ede yii to wa ni ní Falgore, Kano, níbití ikọ ọmọ ogun orilẹ ede yii ti ń gbaradì fún ìdánwò lati gba wọn si isẹ́ ológun.
Igbaradi, eyi ti o jẹ apakan lara akitiyan ile-isẹ ologun orilẹ ede Naijiria ki wọn to bẹrẹ isẹ ologun ni ẹkunrẹrẹ ,ni Falgore, lati jẹ ki awọn oṣiṣe tuntun mọ iṣẹ ti wọn gba ati bi asiko oju ọjọ ṣe n ri, lakoko idanilẹkọọ wọn:
Adari ile-isẹ ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria , wa rọ ikọ ọmọ orilẹ ede yii lati gbaradi fun ipenija to wa niwaju wọn , ni eyi ti o bẹrẹ ni , ọjọ keje, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2021.
O tun tẹsiwaju pe Ile -iṣẹ ọmọ ogun yoo pese awọn ohun elo ati awọn amayederun miran, ti yoo wulo fun aṣeyọri ayẹwo igbanisiṣẹ ti n wọn n se.
Leave a Reply