Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ ọmọ ogun Naijiria gbógun ti ikọ̀ Boko Haram ní Borno

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

56

ikọ̀ ọmọ ogun  orilẹ̀ ede Naijiria ti 25, ẹ̀ka HADIN KAI ti Àríwá Ilà –oòrùn, ti daná ogun ti ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ Boko Haram àti àwọn alakatakiti ẹlẹsin  musulumi  ní ilà oòrùn Áfíríkà nígbá tí wọ́n  gbìyànjú láti dojú kọ ìlú Damboa ní Ìpínlè Borno.

Gẹgẹ bi alaye ti agbẹnusọ ikọ ilé-isẹ́ ọmọ ogun  orilẹ ede Naijiria ọhun ,ọgagun  Onyeama Nwachukwu se sọ pe, awọn janduku  kan gbiyanju lati se isẹ  ibi wọn ni agbegbe ọhu sugọn ti ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria, ti ko figbakan tura silẹ si dada sun wọn.

Agbẹnusọ fun awọn ọmọ ogun naa ṣalaye pe, awọn yoo ri pe, awọn ṣe awari awọn ti o salọ. Bo tilẹ jẹ pe, ni asiko gbọnmisi -omi- o -too ọhun,ti ikọ ọmọ ogun orilẹ ede ati ikọ ọlọtẹ gbena woju ara wọn , ọkọ meji ti o jẹ ti ikọ ọmọ ogun orilẹ ede yii ni wọn dana sun , ti ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria naa , si se wọn bi ọṣẹ se n sojú.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.