Ìjọba ìpínlẹ̀ Niger, ní Àríwá Àárín gbungbun orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà, ti fìdíẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn afipá jínigbé ti gbé Kọmíṣónà fún ìròyìn, Mohammed Sani Idris gbé.
Gẹgẹ bii agbẹnusọ fun Gomina Ipinlẹ naa, Iyaafin Mary Berje se sọ pe , awọn adigunjale ọhun ji Mohammed Sani Idris gbe ni deede agogo kan oru ọjọ aje, ni ile rẹ ni Baban Tunga , ni ijọba ibilẹ Tafa,ni ipinlẹ Niger.
Iyaafin Berje fidi rẹ mulẹ pe, awọn ile -iṣẹ aabo ti bẹrẹ si ni tọpa awọn adigunjale ọhun lati ri pe ọwọ ba wọn.
A yoo ranti pe, ijọba ipinlẹ Niger ti ṣe ifilọlẹ ọlọpa apapọ ati ẹgbẹ alabojuto kan ni agbegbe Kagara ti ipinlẹ naa laipẹ, lati dena idinku awọn iṣẹ ipaniyan ni agbegbe naa.
ile-isẹ akede Naijiria,Voice of Nigeria tun ṣalaye pe, awọn ọmọ ile -iwe Tegina Islamiya aadọje ti wọn ji gbe ni agbegbe ijọba Rafi ti ipinlẹ naa, ko tii gba ominira lẹyin ọpọlọpọ awọn idunadura.
Ijọba ipinlẹ Niger ti kede tẹlẹ pe, ko si ẹnikankan ti yoo sanwo irapada fun itusilẹ lọwọ adigunjale kankan.
Leave a Reply