Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ajínigbé ti jí kọmíṣóna fún ìròyìn ìpínlẹ́ Niger gbé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

62

Ìjọba ìpínlẹ̀ Niger, ní Àríwá Àárín  gbungbun orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà, ti fìdíẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn afipá jínigbé ti gbé Kọmíṣónà fún ìròyìn, Mohammed Sani Idris gbé.

Gẹgẹ bii agbẹnusọ fun Gomina Ipinlẹ naa, Iyaafin Mary Berje se sọ pe , awọn adigunjale ọhun ji Mohammed Sani Idris gbe ni deede agogo kan oru ọjọ aje, ni ile rẹ ni Baban Tunga , ni ijọba ibilẹ Tafa,ni ipinlẹ Niger.

Iyaafin Berje fidi rẹ mulẹ pe, awọn ile -iṣẹ aabo  ti bẹrẹ si ni tọpa awọn adigunjale ọhun  lati ri pe ọwọ ba  wọn.

A yoo ranti pe, ijọba ipinlẹ Niger   ti ṣe ifilọlẹ  ọlọpa apapọ ati ẹgbẹ alabojuto kan ni agbegbe Kagara ti ipinlẹ naa laipẹ, lati dena idinku awọn iṣẹ ipaniyan ni agbegbe naa.

ile-isẹ akede Naijiria,Voice of Nigeria tun ṣalaye pe, awọn ọmọ ile -iwe Tegina Islamiya aadọje ti wọn ji gbe ni agbegbe ijọba  Rafi ti ipinlẹ naa, ko tii  gba ominira lẹyin ọpọlọpọ awọn idunadura.

Ijọba ipinlẹ Niger ti kede tẹlẹ pe, ko si ẹnikankan ti yoo sanwo irapada  fun itusilẹ lọwọ adigunjale kankan.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.