Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹni tí Sango bá tojú rẹ jà,kò ní bá wọn bú ọba kòso,ẹni tí ogun Biafra bá sojú rẹ̀,kò ní gbàdúrà fún ogun abẹ́lé ní Nàíjíríà-Abdullahi Umar Ganduje

130

Gomina ipinlẹ Kano,  Abdullahi Umar Ganduje ti rọ gbogbo awọn to n kọrin pe ki orilẹ ede pín , kí wọ́n gba ìtùbí-ìnùbí laaye , nitori pe ti orilẹ ede Naijiria ba pin, ko ni ṣe ẹnikakan ni anfaani.

Gomina ipinlẹ Kano sọrọ yii lasiko  eto idanilẹkọọ ti ẹgbẹ́ akọroyin fun ẹgbẹ́  oselu , All Progressives Congress, APC  se niluu Abuja.O tẹsiwaju pe

Orilẹ ede  agbaye ko ni bọ̀wọ fún orilẹ ede Afirika mọ̀ ọ́n, ti wahala ba sẹlẹ̀ ni orilẹ ede Naijiria ati pe oloogbe  ‘Mandela  ko ni lee sùn daadaa mọ́, ti a ba kuna lati maa dari awon adulawọ.Idi niyi ti awa ti a jẹ́ adarí gbọdọ se ara wa ni ọ̀kan , ki a ṣi pẹ̀tù si awọn ti inú n bí , ti wọn fẹ́ kí orilẹ ede Naijiria pín.

“ Awọn ajijagbara fun ominira ‘Biafra’  ati awọn ajijagbara fun ominira fun ilẹ̀  Yoruba lati ni orilẹ ede Oduduwa , mọ pe  aarẹ orilẹ ede akọkọ fun orilẹ ede Naijiria ni  Nnamdi Azikiwe,ti o jẹ ẹ̀yà  Igbo , ti o si jẹ ọkan lara awọn ti o gba ominira fun orilẹ ede Naijiria.

“ Bakan naa, ni oloogbe  Obafemi Awolow, ko fi igba kan nifẹẹ si pe ki orilẹ ede Naijria pín.Oun to fẹ ni  pe ki atunse de ba bi wọn se n dari orilẹ ede Naijiria, ko si dakẹ ariwo titi ti o fi jẹ Ọlọrun nípè, ko si ẹni to lee daamu awọn to n fẹ ki atunse de ba bi orilẹ ede Naijiria se wa .Ẹgbẹ oselu APC ti bẹrẹ isẹ lori awọn atunse ti awọn eniyan n pariwo rẹ̀ .Eleyi lo yẹ ki gbogbo wa tẹramọ, ki i se pé ki orilẹ ede Naijiria pín tabi ki awọn eya kan yapa.

Lara awọn ti o tun sọrọ nibi idanilẹkọọ ọ̀hún naa ni,gomina ipinlẹ Imo tẹlẹri ,asofin Rochas Okorocha naa sọ pe awọn ti o mú orilẹ ede Naijiria lẹ́rú , ko fun awọn ọmọ  orilẹ ede Naijiria ni anfaani lati jiroro nipa ibagbepọ wọn , ki wọn to so orilẹ ede Naijiria papọ̀, nitori naa, awọn adari ní isẹ́ púpọ̀ lati se , ki orilẹ ede Naijiria lee wa ni ọ̀kan.

“Ohun to yẹ ki a se ni pe , ki  a wa ojutuu si iwa aparo kan, ga ju ọkan lọ,gẹgẹ bi orilẹ ede , ki a bẹrẹ nipa gbigbogun ti ebi.

“Ki gbogbo awọn to ba di ipo adari mu lorilẹ ede Naijiria ,se orilẹ ede Naijria gẹgẹ bi ẹbí ki i se nipa iwa aparo kan, ga ju ọkan lọ,ni gbogbo ọna , ti o ba mọ ọmọ igbo kan, ọmọ ibo ko beere ohun miran yatọ si pe , ki ẹ jẹ ki gbogbo wa jọ maa jẹ anfaani kan naa.Njẹ ẹ mọ pe , ti gbogbo awọn adari ba n se ohun ti ,Ganduje n se ni ipinlẹ Kano , ti o fun ọmọ ibo ni ipo adari , o di dandan ki orilẹ ede yii wa ni ọkan” .

Alaga fidiẹ fun ẹgbẹ oselu APC , Mai Mala Buni naa tun wa gbosuba fun awọn akọroyin fun ẹgbẹ oselu APC fun gudu gudu meje , yaya mẹfa ti wọn n se lati maa fun awọn eniyan ni iroyin ni gbogbo igba, nipa ẹgbẹ́ wọn. Ken Nnamani lo soju Mai Mala Buni

Asofin Nnamani  sọ pe  bi wọn se n dari eto ijọba orilẹ ede Naijiria lo ti  mẹ́hẹ, eyi lo faa ti awọn eniyan se n pariwo pe , awọn fẹ́ yapa kuro ni orilẹ ede Naijiria.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.