Igbákejì ààrẹ Yemí Òsìńbàjò ti tẹnumọ́ akitiyan Ìjọba àpapọ̀ pé, òhun kò ní fi ààye gba ìwà ìfipá mú ènìyàn (GBV) tí ó sì tún mu dájú pé ,irú ẹni tí wọ́n bá fi ìyà náà jẹ yóò rí eto ààbò àti ìdájọ́ òdodo gbà.
Igbakeji aarẹ ṣalaye eyi ni ọjọ iṣẹgun, lakoko ti o n ṣe ifilọlẹ USAID’s MOMENTUM ti Orilẹ -ede ati iṣakoso Agbaye (MCGL) ni ilu Abuja.
Igbakeji aarẹ Ọsinbajo, ti minisita fun ọmọniyan,iṣakoso ajalu ati idagbasoke awujọ, Sadiya Umar Farouk ṣoju, sọ pe GBV wa nipasẹ awọn aidogba igbekalẹ ati agbara ajọṣepọ aiṣedeede ti o jẹ ki awọn obinrin wa labẹ awọn ọkunrin.
O salaye pe eyi waye bẹẹ nitori pe diẹ ninu wọn ni o ni anfaani si ẹkọ,iṣẹ-ṣiṣe,eto inawo,ilera ati anfaani lati gbaruku ti ẹbi,agbegbe ati idagbasoke eto -ọrọ aje orilẹ -ede wọn.
O ṣe akiyesi pe iru awọn idi yii maa n fa idiwọ fun awọn eniyan wọnyii, awọn ẹbi, awujọ ti yoo si tun fa ifasẹyin fun ọrọ -aje orilẹ -ede wọn.
Leave a Reply