Àjọ ẹgbẹ́ aṣàgbéyẹ̀wò ọmọ Yorùbá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àjọ àgbáyé UN lórí ààbò Nàìjíríà
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ẹgbẹ́ kan, àjọ aṣàgbéyẹ̀wò ọmọ Yorùbá, YAF ti kọ ìwé ẹ̀bẹ̀ sí àjọ àgbáyé UN, EU àjọ aláwọ̀ funfun àti àjọ adúláwọ̀ AU,láti ran àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò orílè-èdè Nàìjíríà lọ́wó lórí àwọn tí wọ́n ń gbèrò láti dá làásígbò sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè lórúkọ àtimú ìpinnu ara ẹni ṣẹ lóríi yorùbá.
YAF pe akiyesi awọn ẹgbẹ kariaye wọnyi si igbesẹ ti ẹgbẹ kan, ti wọn n pe ni : Ilana Omo Oodua n gbe lati fi ẹjọ ijọba Naijiria lọ sun Apejọ Gbogbogbo ti Ajo Agbaye UN.
Ninu alaye atẹjade kan ti oludari gbogbogbo YAF buwọlu , Ọgbẹni Adeshina Animashaun, YAF sọ pe ki UN maa ṣe jẹ ki ẹgbẹ naa o wa nijoko nibi apejọ ẹlẹẹkẹrin-din-lọgọrin UNGA.
Ọgbẹni Animashaun sọ pe, ẹgbẹ Ilana Omo Oodua duro niduro ati ba ijọba Naijiria jẹ ni.
Ẹgbẹ naa ṣafikun pe orilẹ -ede Yoruba ko gbegbesẹ kankan lati yapa kuro ni orilẹ -ede Naijiria ati pe o pinnu lati jẹ ara orilẹ -ede Naijiria.
Leave a Reply