Take a fresh look at your lifestyle.

ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸRIKA YÓÒ sèrànwọ́ fún ORÍLẸ̀-ÈDÈ SUDAN láti ní ìdàgbàsókè lori ètò ọrọ̀ ajé

0 327

Orílẹ̀-èdè Amẹrika ti sọ pé àwọn yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Sudan láìmọye ọ̀nà lóri bí wọ́n yóò se mú ìdàgbàsókè bá ètò ọrọ̀ ajé wọn àti àwọn ohun mííràn tí  yóò mú ìdàgbàsókè bá àwọn ènìyàn.
Asoju Orilẹ-ede Amẹrika lori eto  Ile-iṣẹ ati  idagbasoke fun ajọ agbaye  ni ilẹ Amẹrika (USAID), iyaafin SAMANTHA POWER  lo salaye yii lakoko ti o se abẹwo lọ si orilẹ-ede Sudan, O tun se akiyesi pe orilẹ-ede Sudan nilo iranlọwọ lori eto ọrọ-aje ati  fun awọn eniyan ni kiakia.
Orilẹ-ede Sudan ti n ri ayipada nipasẹ oṣelu ati eto-ọrọ aje lati igba ti aarẹ Omar al-Bashir ti kuro ni aarẹ ni Oṣu Kẹrin Ọdun 2019, USAID sọ pe awọn orilẹ-ede  to wa ni iwọ oorun Ariwa  ti setan lati ṣe atileyin fun awọn ọmọ orilẹ-ede Sudan.

Hamzat Damola

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button