Take a fresh look at your lifestyle.

lílo ìmọ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ètọ ìjọba yóò mú ìdàgbàsókè ba Nàíjíríà- Isa Pantami

54

Ijọba apapọ orilẹ ede Naijiria ti se ifilọlẹ eto imọ ẹrọ igbalode fun ijọba ipinlẹ Kano ,to wa ni iwọ orrun Ariwa orilẹ ede Naijria.

Ijọba ipinlẹ Kano , ni yoo kọ́kọ́ jẹ anfaani  eto imọ ẹrọ ti ijọba apapọ se yii.

Eto imọ ẹrọ igbalode yii ni ijọba apapọ seto lati kọ́ awọn to n dari eto ijọba ipinlẹ nipa lilo imọ ẹrọ lati mu idagbasoke ba gbogbo ìpele ijọba to wa lorilẹ ede Naijiria, ki o le din eto ìnáwó kù.

Bakan naa, ni yoo tun jẹ ki ibasepọ to wa laarin gbogbo ipele ijọba to wa jake jado orilẹ ede Naijiria, nípa lilo imọ ẹ̀rọ igbalode.

Minisita fun imọ ẹrọ ati lilo imọ ẹrọ fun eto ọrọ̀ ajé lorilẹ ede Naijiria, Isa Pantami  ati gomina ipinlẹ Kano,Abdullahi Umar Ganduje  lo se ifilọlẹ yii.

Pantami  wa gbosuba fun ipinlẹ Kano fun igbesẹ ti wọn gbe lati mu idagbasoke bá ipinlẹ Kano.

Minisita tun tẹsiwaju pe ajọ wọn ti setan lati tun fọwọsowọpọ pẹlu gbogbo ipinlẹ  ati ijọba ipinlẹ lati pese ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ igbalode fun wọn.

Gomina ipinlẹ Kano, Ganduje  wa fi idunnu rẹ han fun eto iranwọ ẹ̀kọ imọ ẹrọ ayelujara  ti ajọ to n samojuto imọ ẹrọ ati lilo imọ ẹrọ igbalode fun eto ọrọ aje pèsè fun ọgọrun un awọn ọ̀dọ́.

Leave A Reply

Your email address will not be published.