Take a fresh look at your lifestyle.

COVID-19: Nàíjíríà yóò tún bẹ̀rẹ̀ ìpéle gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára Corona míràn

56

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ti ní àwọn  ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà kò ní  pẹ́ bẹ̀rẹ̀ si ní máa gba abẹ́rẹ́ àjẹsára  COVID-19.

Minisita fún ètò ìlera, lorilẹ ede Naijiria, Osagie Ehanire  lo kede eyi niluu  Abuja,lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ nibi ipade ti wọn maa n se pẹlu awọn akọroyin.

O tẹsiwaju pe  awọn yoo mu ipinnu yii sẹ  nipa igba-ọ̀kẹ́-lé-ni-ọrín (4,000,080) abẹrẹ ajẹsara Moderna ti  orilẹ ede Amerika fi ta wọn lọ́rẹ.

Ajọ  NAFDAC. si n se ètò àyẹ̀wọ  lori  abẹrẹ ajẹsara ti wọn gba yii, ki ọdun yii to pari , orilẹ ede Naijiria yoo ti gba ogoji miliọnu abẹrẹ ajẹsara ”.

Dokita  Osagie tun tẹsiwaju pe ile-iwosan alabọde  ni yoo maa pin  awọn abẹrẹ ajẹsara yii kaakiri gbogbo ipinlẹ to wa lorilẹ ede Naijiria.

O wa rọ gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijria, lati lọ gba abẹrẹ ajẹsara ọhun, fun idaboobo ara wọn ati ilera wọn.

o tẹsiwaju pe  “Ẹ̀rí ti fihan nibi ti wọn ti n gba itọju arun COIVD-19 pe gbogbo awọn to n padanu ẹmi wọn nipa arun COVID-19 , ni awọn eniyan ti wọn ko tii gba abẹrẹ ajẹsara ọhun.O wa rọ gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijria lati lọ gba abẹrẹ ajẹsara ọhun, gẹgẹ bi ojuse wọn ati lati daabobo  awọn olufẹ ati ara wọn ”.

Leave A Reply

Your email address will not be published.