Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ jẹ́ ká sàtìlẹ́yìn fún ìjọba Buhari láti túbọ̀ mú ìpinnu rere rẹ̀ sẹ ní Nàíjíríà -NLID

75

Awọn ọmọ orilẹ ede Naijria to n gbe ni òkè-òkun  ti rọ awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria nile ati lókè òkun  lati tubọ maa satilẹyin fun ijọba  aarẹ Muhammadu Buhari fun gudu gudu meje, yaya mẹfa ti wọn n se lati mu idagbasoke ba orilẹ ede yii.

Ninu atẹjade kan ti ọjọgbọn  Peter Otah, akọwe  ẹgbẹ awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria ti wọn n gbe loke-okun( Nigerian Leaders in Diaspora ,NLID),gbe jade  lasiko ètọ ìwọ́de niluu London  ni  United Kingdom se.

Ẹgbẹ́  NLID  ni isọkan ati alaafia nikan lo lee mu idagbasoke ba orilẹ ede Naijria.Wọn tẹsiwaju pe awọn se iwọde yii lati satilẹyin fun ile-isẹ́ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria  ati lati gbadura fun isọkan orilẹ ede Naijiria paapaa julọ lasiko ti orilẹ ede Naijiria n dojukọ ipenija lori eto aabo.

Ọgbẹni Ade Omole,ni  anfaani nla lo jẹ fun orilẹ ede  Naijiria lati ni Muhammadu  Buhari gẹgẹ bi  aarẹ orilẹ ede Naijiria.

O tẹsiwaju pe bo tilẹ jẹ pe orilẹ ede Naijiria n dojukọ ipenija  bayii sibẹ nipa isọkan ati afojusun rere , Naijiria  yoo si wa ni ọ̀kan , eniyan kan ati orilẹ ede ti ko see ni pin yẹ̀lẹ-yẹ̀lẹ.

Ọgbẹni Talba Galadima,naa tun sọ pe  idagbasoke to ti de ba orilẹ ede Naijiria lati bi ọdun mẹrin sẹyin ti aarẹ Buhari ti de sori aleefa ko lonka.

Iyaafin Edith Nwachukwu, ni irinsẹ ogun ti aarẹ Buhari ra fun awọn ile-isẹ ologun  jẹ igbesẹ nla lati pa ti ikọ ọlọtẹ  run lorilẹ ede Naijiria.

Leave A Reply

Your email address will not be published.