Take a fresh look at your lifestyle.

Igba miliọnu dọla la ó ná síbi ètò ìlera ní Nàíjíríà, a ó sì tún kọ́ ogún ilé ìwòsàn àrùn jẹjẹrẹ-Uche Orji

105

Ajọ to n mojuto ọrọ to jẹ mo eto okoowo lorilẹ ede Naijria, (The National Sovereign Investment Authority NSI) ti ni awọn yoo na igba miliọnu  dọla, owó ilẹ̀ okeere ($200 million)  lori eto ilera  ní orilẹ ede Naijiria.

Oludari ajọ ọhun, Uche Orji  lo sọrọ yii lọjọBọ  niluu Abuja lẹyin ipade igbimọ awọn minisita lorilẹ ede Naijiria .

O ni awọn yoo pese owo ọhun  nipasẹ ifọwọsowọpọ pẹlu awọn to nifẹẹ lati fowo wọn se okoowo lori eto ilera , ni eyi ti awọn yoo bẹrẹ isẹ́ lori rẹ ni ọdún yii.

“Pupọ lara awọn ile iwosan to wa lorilẹ ede Naijiria ni ko bojumu  rara.Awọn yoo tun  awọn ile-iwosan igbolode miran kọ́,  bi  ti ile -iwosan arun jẹjẹrẹ to wa nile ẹkọ ti iwosan Fafiti ti ilu  Eko”.

Uche Orji  tun tẹsiwaju pe “ Inu mi dun pe a ti se aseyọri lori awọn ile-iwosan yii.Nigba ti a bẹrẹ lati maa kọ awọn ile-iwosan tuntun yii, a gba awon osisẹ lati orilẹ ede South Africa, sugbọn pàbó ló jasi, ni a ba jawe duro sile fun wọn, a da wọn duro,ki o to di pe, a wa gba awọn  osisẹ to jẹ ọmọ orilẹ ede tiwa, ni eyi ti o jẹ pe wọn n se isẹ́ ti a fẹ, fun wa .

Awọn ile -iwosan fun arun jẹjẹrẹ

 

Uche Orji  tun sọ pe  awọn yoo bẹrẹ lati maa kọ ile iwosan fun arun jẹjẹrẹ ogún (20) ni awọn ipinlẹ jakejado lorilẹ ede Naijiria.

“Ipinnu wa ni lati kọ ile iwosan ogún (20) fun itọju arun jẹjẹrẹ ni jake- jado orilẹ ede Naijria, A o bẹrẹ pẹlu mẹta lọdun yii ; A o kọ ile-iwosan meje lọdun ti o ba tẹle, a o si tun kọ mẹwaa lọdun miran . Gbogbo ile -iwosan fun itọju arun jẹjẹrẹ ti a o kọ ni yoo jẹ ti igbalode  , ti yoo si tun lee wa ibamu pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ni agbaye,”. 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.