Ìṣòwò orí ayélujára: Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò jàǹfààní ìpàtẹ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ Ìmọ̀-ẹ̀rọ orí òkun
Eyitay Fauziat Oyetunji
Ìjọba Nàìjíríà yóò jàǹfààní níbi ìkópa rẹ̀ níbi Àfihàn Ìmọ̀-ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lórí omi òkun (GITEX) 2021 láti túnbọ̀ ṣàwárí àjọṣepọ̀ káríayé fún ìyípadà orílẹ̀-èdè lórí ọrọ̀ ajé orí ayélujára àti àtìlẹ́yìn fún ìgbèrú ẹ̀dá abẹ̀mí-ayé rẹ̀ ti ń dàgbà.
Oludari Gbogbogbo, Ile-iṣẹ Idagbasoke Imọ-ẹrọ ibaraẹnisọrọ orilẹ-ede (NITDA), Kashifu Inuwa,ni o sọ eleyi di mimọ lakoko ti o n fi Igbimọ Agbegbe (LOC) fun GITEX 2021 lọlẹ, ni ilu Abuja.
O rọ awọn ọmọ ẹgbẹ LOC lati jẹ alailẹgbẹ ati pe ki wọn tun ṣawari awọn ọna tuntun lati mu daju pe eto naa bori awọn to ti ṣiwaju.
LOC ni awọn aṣoju lati Awọn ile-iṣẹ ti o jẹ mọ ọrọ eto ibaraẹnisọrọ ayelujara, Awọn ẹka ati Awọn ile-iṣẹ (MDAs), pẹlu igbimọ to n mojuto eto ati iṣe orilẹ-ede (NIMC), Igbimọ eto ibaraẹnisọrọ orilẹ-ede (NCC), ati NIGCOMSAT ati awọn ile-iṣẹ aladani.
Leave a Reply