Take a fresh look at your lifestyle.

COVID-19: Àwọn ènìyàn mèjì-le-ni-ojì din ni ẹgbẹ́ta míràn ló tún ti ní ààrùn covid báyìí

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

119

Ééjì-lé-ní-òjì dín ní ẹgbẹ̀ta ènìyàn míràn ni ààrùn covid tún ti jẹyọ lára wọn,ní báyìí, àwọn tó ti  ní ààrùn ọ̀hún jẹ́ ọgọ́rún kan àti ààdọ́rin ó lé mẹ́jọ, ẹgbẹ̀rin àti mọ́kànlélógún.

Ile-iṣẹ to n mojuto ajakalẹ aarun ni orilẹ-ede (NCDC) ṣe ikede rẹ ni ọgbọnjọ,ọjọ ẹti ọdun 2021.

Gẹgẹ bii NCDC ṣe ṣalaye,awọn eniyan meji-le-ni-oji din ni ẹgbẹta yii wa lati ipinlẹ mẹrin-din-logun-Lagos (ọ̀ọ́dúnrún ó dín mẹ́rin),Akwa ibom(mẹrin-din-lọgbọn),FCT(mẹji-le-logun),Imo(mẹẹdogun),Bayelsa(mẹtala),Kano(mejila),Ogun(mọkanla),Plateau(mọkanla),Delta(mẹsan),Jigawa(mẹfa),Rivers(mẹrin),Zamfara(mẹrin),Edo(meji),Ebonyi(eyọkan).

Ile-iṣẹ to n mojuto ajakalẹ aarun ọhun sọ pe ni ọjọ kọkan-din-lọgbọn,oṣu keje,eniyan ọgọrun kan ati adọrin- le-mẹjọ,ẹgbẹrin ati mọkan-le-logun lo ti ni aarun ọhun bayii,ẹ̀ẹ́dẹ́gbàta le ni ọ̀kẹ́ mẹ̀jọ o din ni ọ́rin-din-lẹwá si ti gba iwosan,ti eniyan ọ̀kan-le-ni-ojì le ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ọ̀kànlá si ti jẹpe oluwa.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.