Take a fresh look at your lifestyle.

Àpèjọ Àgbáyé: Ààrẹ Bùhárí Tẹnumọ́ Pàtàkì Ẹ̀kọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

80

Ààrẹ̀ Mùhámmádù Bùhárí ti kéde pé, òbí kankan kò yẹ kí ó fi ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ṣe àwàdà,  nítorí pé tí  àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ tí wọ́n gbà tọ́ bá pàdánù láti kọ́ ẹ̀kọ́, wọ́n pàdánù púpọ̀.

Nigbati o nsoro lakoko apejọ  kan ni Ọjọbọ, nibi Apejọ Ẹkọ Agbaye ni Ilu Lọndọnu, aarẹ sọ pe, iwọn ati bi eniyan ṣe pọ si ni orilẹ-ede Naijiria jẹ awọn italaya fun eto iṣakoso, ṣugbọn sibẹsibẹ, ijọba ati awọn eniyan mọ pe eto-ẹkọ ni ibẹrẹ  aṣeyege.

 

Awọn ti o wa nibi apejọ ọhun pẹlu Aarẹ Buhari ni:  aarẹ Nana Akufo-Addo ti Ghana, Faure Gnassingbe ti Togo, Uhuru Kenyatta ti Kenya, ati Lazarus Chakwera ti Malawi

Enikọọkan wọn  sọrọ lori awọn iyatọ ti eka eto-ẹkọ  orilẹ-ede rẹ ni, ati bii awọn ipese eto-inawo yoo ṣe pọ si lati ṣe atunṣe lori rẹ . Gbogbo wọn gbe ọwọ wọn soke gẹgẹ bi ami  ifaramọ si ipinnu naa.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.