Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari kí gómina Akeredolu kú orí ire

106

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjjíríà, Muhammadu Buhari ti  darapọmọ awọn akẹgbẹ rẹ ninu ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC) latí kí gomina ìpínlẹ̀ Ondo,Rotimi Akeredolu bi o se tun jawe olubori nile ẹjọ to ga julọ lorilẹ ede Naijiria gẹgẹ bi gomina tó pegedé, ni eto idibo gomina ti wọn di ni ọjọ kẹwaa osu kẹwaa , lọdun 2010.

Aarẹ  Buhari wa rọ gomina ọhun ati awọn adari ẹgbẹ oselu APC , ki wọn maa jẹ ki ifẹ ọkan awọn eniyan wa oókan àyà wọn ju ti ìfẹ́  ara wọn lọ.

Aarẹ wa tẹsiwaju pe ẹgbẹ oselu APC yoo tubọ maa tẹsiwaju sii , ni eyi ti yoo maa tun jẹ ki awọn oludibo tun nifẹẹ si wọn.

Aarẹ Buhari wa rọ gomina ipinlẹ Ondo lati tubọ maa tẹsiwaju nipa awọn isẹ́ rere rẹ lati lee jẹ ki idagbasoke tubọ ba ipinlẹ naa, ni eyi ti  ro yan awọn olùdókoòwò  lọwọ lati lee se  okoowo  wọn ni ipinlẹ naa, ki o si tun tubọ mu eto ẹ̀kọ́, ilere ati eto aabo ni ọkunkundun.

Aarẹ  wa rọ gbogbo awọn ẹgbẹ alatako lati darapo gomina Akeredolu ti ipinlẹ Ondo ni eyi ti idagbasoke yoo se de ba ipinlẹ naa.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.