Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ jẹ́ asojú rere,kí ẹ sì máa sọ òtítọ́ nípa ohun tó ń sẹlẹ̀ ní Nàíjíríà nílẹ̀ òkèèrè – Lai Mohammed

187

Ijọba orilẹ ede Naijiria  ti pàrọwọ̀  fun awọn ẹgbẹ  awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria to n gbe nilẹ okeere iyẹn, the Nigerians in Diaspora Organisation, NIDO  lati jẹ asoju rere nilẹ okeere, ki wọn si maa lu oju abẹ́ níkòó lati maa sọ otitọ nipa ohun to n sẹlẹ lorilẹ ede Naijiria.

Minista fun eto iroyin ati asa lorilẹ ede Naijiria,Alhaji Lai Mohammed lo sọrọ niluu Abuja lọjọ  Isẹgun lasiko ti ẹgbẹ  NIDO  se ẹ kare, ẹ n lẹ nibẹ yẹn sii..

Alhaji Mohammed  tun wa rọ ẹgbẹ naa lati maa jẹ asiwaju rere , ki wọn si maa  tako awọn ti wọn ba fẹ maa ba orukọ orilẹ ede Naijiria jẹ́.

Minisita tun tẹsiwaju pe , bo tilẹ jẹ pe orilẹ ede Naijiria  n koju ipenija nipa eto aabo sibẹ ,ọpọlọpọ ohun ribiribi ni ijọba apapọ ti se lati mu  eto  idagbasoke ba  orilẹ ede Naijria.

Alaga ẹgbẹ  NIDO,to wa ni UK , ọgbẹni  Chubuzo Obochi  naa sọ pe ẹgbẹ wọn ti ya ọsẹ kan sọtọ lati maa sọ nipa ohun ribiribi ti orilẹ ede Naijiria ti gbese lati mu idagbasoke ba orilẹ ede yii.

O tẹsiwaju pe digbí ni ọmọ ẹgbẹ wọn wa lati maa pese ohun to le mu idagbasoke ba orilẹ ede Naijiria, o wa rọ ijọba apapọ  lati ṣe eto ti yoo maa je ki awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria  kopa pataki  lorilẹ ede yii paapaa julọ awọn ọmọ orilẹ ede Naijria to n gbe nilẹ okeere  .

Leave A Reply

Your email address will not be published.