Take a fresh look at your lifestyle.

A ó tẹ̀síwájú láti máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Spain nínú ètò ọ̀gbìn, ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé- Buhari

54

Ààrẹ  Muhammadu Buhari  ti ní orílẹ̀ èdè Naijiria yoo tubọ maa fọwọ́sowọ́pọ̀  pẹlu orilẹ ede Spain lati lee tẹpẹlẹmọ ibasepọ to wa laarin awọn orilẹ ede méjéèjì.

Aarẹ sọrọ yii lasiko ayẹyẹ idagbere ti wọn  se fun asoju orilẹ ede Spain, Marcelino Cabanas Ansorena  ati asoju orilẹ ede  Qatari , Abdulaziz Mubarak Al Muhanadi niluu Abuja , ti wọn  n fi orilẹ ede Naijria lọ si ilu wọn .

Ansorena  naa wa salaye pe ọdun mẹrin ti o lo lorilẹ ede Naijiria  jẹ iriri mále gbàgbé ati pe ibasepọ to wa laarin orilẹ ede   Naijria ati Spain yoo tubọ maa tẹsiwaju sii.

Ansorena wa gbosuba fun  aarẹ Buhari nipa eto idagbasoke ti o ti de ba eto ijọba tiwa-n-tiwa lorilẹ ede Naijiria.

Asoju orilẹ ede  Qatar  ti  oun  naa  n fi orilẹ ede Naijria  silẹ ,Abdulaziz Mubarak Al Muhanadi, naa wa salaye pe ibasepọ to wa laarin orilẹ ede Naijria ati Qatar yoo tubọ maa tẹsiwaju sii nipa epo rọbi .

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.