Take a fresh look at your lifestyle.

Gomina Umahi pé ọmọ ọdún méjìdínlọ́gọ́ta, ààrẹ Buhari kí Umahi ku orí-ire

41

Aarẹ  Muhammadu Buhari ti bá gomina ipinlẹ Ebonyi ku ori ire ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun méjìdínlọ́gọ́ta ti o pé léèpẹ̀ alàyè  ni ọjọ́ karundinlọgbọn , osu keje ọdun, 2021.

Ninu atẹjade kan ti aarẹ Buhari fi ransẹ si gomina ọhun, aarẹ sapejuwe gomina naa gẹgẹ bi “ọkunrin to ni igboya,”  ti kii kuna lati tẹle ọkàn rẹ̀ , nipa jijẹ olufọkansin fun awọn eniyan rẹ̀.

Aarẹ wa ba gbogbo ẹbí  Umahi , ọrẹ ati awọn alabasisẹpọ rẹ yọ̀ , aarẹ Buhari wa gbadura fun gomina ti o jẹ ọmọ ẹgbẹ APC  naa pe , Ọlọrun yoo fun gomina naa ni okun ati agbara lati tubọ lee sin awọn eniyan rẹ̀.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.