Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ọba Yorùbá ní orílẹ̀ èdè Benin fẹnukò lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho

28

Awọn ọba ti ilẹ Yoruba lorilẹ ede Benin ti ṣe ipade ni aafin aladjohoun ti ilu Adjohoun lorilẹ ede Benin lọjọ Aiku yii.
Ohun ti ipade wọn naa da le lori ni ọrọ Sunday Adeyẹmọ ti a mọ si Sunday Igboho.

Lọjọ aje ni oloye Sunday Igboho yoo pada foju ba ile ẹjọ lorilẹ ede Benin lati mọ boya wọn yoo tuu silẹ ni tabi ki wọn daa pada sorilẹ ede Naijiria gẹgẹ bi ijọba orilẹ ede Naijiria se fẹẹ.

Lẹyin ipade to pari ni deede agogo meji ọsan ti aago orilẹ ede Naijiria, awọn ọba naa ṣalaye pe ipade naa wa lati mọ ọna abayọ ati igbesẹ ti wọn yoo gbe lori ọrọ naa ni. Wọn ni ohun ti awọn fi ẹnu ko le lori ni lati kọ iwe si aarẹ orilẹ ede Benin pẹlu minisita fun eto idajọ, minisita to n mojuto ọrọ abẹle ati olori ile egbimọ aṣofin apapọ lorilẹ ede naa.

Ọba Siyan aladjohoun ti ilu Adjohoun ṣalaye pe awọn ọba alaye naa yoo tun gbiyanju lati ṣe abẹwo si ile ijọba orilẹ ede Benin ni ọjọ Aje bi esi iwe ti wọn ba kọ, ko ba tete jade.

Leave A Reply

Your email address will not be published.