Take a fresh look at your lifestyle.

A ó ran orílẹ̀ èdè Nàíjíríà lọ́wọ́ láti mójútó ètò ààbò tó mẹ́hẹ -AFRPN

47
Ẹgbẹ́  awọn onimọ lori ibasepọ pẹlu ọrọ to jẹ ti okeere lorilẹ ede Naijiria,(AFRPN),  ti ni awọn ti setan lati ran  ijọba orilẹ ede Naijiria lọwọ lori eto aabo to mẹhẹ nipa lilo itubi-inubi.
Aarẹ ẹgbẹ AFRPN, Gani Lawal, lo sọrọ yii pẹlu awọn akọroyin niluu Abuja  ni igbaradi fun eto idanilẹkọọ ọdọọdun ti wọn maa n se  , ni eyi ti wọn pe akọle ti ọdun yii ni : “ Lilo eto  itubi-inubi lati gbogun ti iwa ọdaran ati idunkooko mọni nilẹ Afirika.
 Lawal tun tẹsiwaju pe awọn mu akori  ti ọdun yii lati lee jẹ ki awọn eniyan ri ẹkọ kan kọ nipa lilo ọna itubi-inubi  lati yanju iwa ọdaran ati wahala to maa n sẹlẹ ni awujọ.
Ipade ọhun yoo waye niluu Abuja  ni ọjọ kọkandinlọgbọn , osu keje , ọdun ,2020, ni eyi ti awọn eniyan pataki yoo wa nibẹ, lara wọn ni oludari osisẹ fun aarẹ Buhari , Ibrahim Gambari;minisita fun ọrọ to jẹ mọ ti ilu okeere, Geoffrey Onyeama;minisita ipinlẹ fun ọrọ to jẹ mọ ti ilu okeere, Zubairu Dada;  minisita fun ọrọ to jẹ mọ ti ilu okeere tẹlẹri ,ọjọgbọn Joy Ogwu; asoju orilẹ ede United Kingdom tẹlẹri ,  Dalhatu Tafida, ati awọn miran.
Gbogbo awọn asoju orilẹ ede  kọọkan to wa lorilẹ ede Naijiria,awọn adari ile igbimọ asoju-sofin  ati  bẹẹ bẹẹ lọ.
Leave A Reply

Your email address will not be published.