Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari ti padà sí ìlú Abuja láti Daura, ní ìpínlẹ̀ Katsina

51

Aarẹ orilẹ ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti pada si ilu Abuja, to jẹ olu ilu orilẹ ede Naijiria lẹyin ọjọ mẹjọ ti o lo ni ipinlẹ re iyẹn  ipinlẹ Katsina , nibi ti o ti lọ ba wọn se ayẹyẹ ọdun Eid al-Adha  ni ilu rẹ to wa ni Daura.

Aarẹ lo asikọ ọ́un lati fi se ifilọlẹ   isẹ akanse omi Zobe ni eyi ti  yoo maa pese omi fun aadọta miliọnu awọn eniyanni ipinlẹ naa, bakan naa, ni pipese ohun ọgbin ati isẹ agbẹ fun ọkẹaimọye awọn eniyan lati din ìsẹ́ ati òsì kù ni ipinlẹ naa.

ki aarẹ Buhari to kuro ni ipinlẹ katsina, ni o tun lo anfaan ọhun lati pese maalu meji fun awọn agunbanirọ to wa ni ipinlẹ naa.

Bakan naa, ni aarẹ Buhari tun gbalejo awọn oludari ile igbimọ asofin, Femi Gbajabiamila  ati awon gomina mejila to wa ni ẹgbẹ oselu APC  naa tun wa ki aarẹ ku ọdun ileya ni ilu Daura.

Leave A Reply

Your email address will not be published.