Olùdarí ilé-isẹ́ ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàíjíríà lórí ètò ààbò , ọ̀gágun Lucky Iraborti fọkàn gbogbo àwọn olùgbé ẹkùn ilà òòrùn Gusu balẹ̀ pé àwọn kò ní káàárẹ̀ láti túbọ̀ máa pèsè ètò ààbò níbẹ
Ọgagun Irabor sọrọ idaniloju yii lọjọ Ẹti nigba ti o n ba awọn to fẹyinti ninu isẹ́ ologun to wa ni ẹkun ila Gusu sọrọ , ni ilu Owerri ni ipinlẹ Imo.
Irabor tẹsiwaju pe ile-isẹ ologun pẹlu ajọsepọ awọn agbofinro ti n se gudu gudu meje, yaya mẹfa lati ri i pe eto aaboo jọba ni ẹkun ila oorun Gusu orilẹ ede Naijiria.
Ọgagun Irabor tun sọ pe gbogbo awọn to n se atilẹyin fun awọn to n lu ìlù ogun ni ẹkun ila oorun Gusu orilẹ ede Naijiria ko ni imọ ti o to nipa rẹ̀.
.