Take a fresh look at your lifestyle.
Democracy

Olùdarí Ilé Aṣòfin Èkó rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà láti gba àlàáfíà láàyè

Lanre Lagada-Abayomi

0 253

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ajayi Ọbasa ti rọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati ri wiwa ni alaafia gẹgẹ bi ohun elo to le fẹsẹ oṣelu tiwa-n-tiwa mulẹ.

Aṣofin Ọbasa sọrọ yii ninu ọrọ ikini rẹ fun ayẹyẹ ọdun Ileya tọdun 2021 yii, paapaa fun awọn olugbe ati awọn oloṣelu ni ipinlẹ Eko ti wọn n palẹmọ fun eto idibo ijọba ibilẹ.

Oludari naa woye pe bibeere fun igbe-aye rere lọwọ ijọba jẹ igbesẹ to dara, ṣugbọn lilo ipá lati fi beere ko le ṣe iranlọwọ kankan fun awọn ara ilu ati orilẹ-ede yii. O ni:

“A n ṣaroye nipa ọrọ-aje to mẹhẹ bayii, ṣugbọn bi a ba foju inu wo o, awọn ohun pataki to ṣokunfa eyi ni laasigbo, iwa idigunjale, idunkookomọni, ijinigbe ati aisi aabo kaakiri. Ko si  orilẹ-ede to le goke agba bi laasigbo ba wa bayii. Bi a ṣe wa n rọ awọn ara ilu lati wa lalaafia ati irẹpọ, bẹẹ lawa naa gẹgẹ bi olori ko gbọdọ sun lati maa wa gbogbo ọna ti idagbasoke yoo fi ba orilẹ-ede yii.

“Ni ilu Eko, a ti fapẹẹrẹ rere lelẹ fun eto oṣelu tiwa-n-tiwa to fẹsẹ mulẹ, a si dupẹ lọwọ awọn olori wa ati awọn olugbe to jẹ olododo ni ipinlẹ yii fun aṣeyọri eyi. Bi eto idibo ijọba ibilẹ ṣe wa n bọ lọna yii, o ṣe pataki pe ka ma lọwọ ninu laasigbo kankan.

“A gbọdọ fun awọn ara ilu laaye  lati pinnu yan awọn olori ti wọn fẹ nipo fun ọdun mẹrin miiran. Fun idi eyi, gbogbo wa gbọdọ fọwọ sowọpọ bẹnu atẹ lu ohunkohun to ba nii ṣe pẹlu laasigbo, ki a le yẹra fun ohun to le tẹyin eyi jade.”

Oludari Ile Aṣofin naa sọ eyi, nigba ti o n ki awọn musulumi lorilẹ-ede yii ku ayẹyẹ ọdun Ileya miiran to ṣoju ẹmi wọn.

Leave A Reply

Your email address will not be published.