Take a fresh look at your lifestyle.
Democracy

Ẹ ṣe àtúnse si òfin orílẹ̀ èdè Nàíjiria, láti fòpin sí wàhálà tó ń sẹlẹ̀-ọ̀jọ́gbọ̀n Sabit Olagoke

0 174

Gbajú gbajà olórí ẹlẹ́sìn àti olùdásílẹ̀ Shafaudeen nínú ẹ̀sìn Islam, ọ̀jọ́gbọ̀n onímọ̀ ẹ̀rọ, Sabit Olagoke ti ké sí ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà láti se àgbéyẹ̀wò òfin orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ní ọ̀nà láti fi òpin sí onírúurú ìsoro tó ń súyọ látàrí àírísẹ́ àwọn ọ̀dọ́ jákèjádò orílẹ̀ èdè Nàíjíríà .

Ojogbon Sabit Olagoke lo so ọrọ yii di mimọ lasiko to n se ifọrọwerọ pẹlu ẹgbẹ́ akọroyin ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, eto to waye ni Ile- ẹgbẹ awọn akọroyin ohun to kalẹ si agbegbe Mọkọla ni ilu Ibadan,ipinlẹ Ọyọ, ni ẹkun gusu iwọ oorun orílẹ̀ èdè Nàíjíríà.

Nigba ti o salaye lori idi rẹ ti awọn eya kan se n pariwo iyapa kuro lara orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Ojogbon Olagoke jẹ ki o di mimọ pe, ìsẹ́ ohun òsì ti da’so bo opolopo ọ̀dọ́ lọrun, ninu eyi to faa ti àwọn ẹ̀yà kan se ń kigbe iyapa sugbọn ti ijọba ba le se agbeyẹwo òfin orílẹ̀ èdè Nàíjíríà loju’na ati se atunse to yẹ, ko ni si pe a n kọrin iyapa mọ́ nitori oju n pọ́n ọpọlọpọ ọdọ laarin awọn eya kan ni orílẹ̀ èdè Nàíjíríà.

O wa fi asiko naa rọ ijoba apapo ati ẹya Oodua to n lepa ati ya kuro lara orílẹ̀ èdè Nàíjíríà lati ranti ọna ti orile ede alawọ funfun, Britain gba ki wọn to le da duro.
Ninu ọrọ rẹ, ọjọgbon Olagoke sọ wi pe ” ….ka sisẹ lori pe ta ba da duro, kinni a ni nilẹ to lee gbewa ro,…sugbọn ti ijọba bale sise lori ohun meje ti awon odo n so lasiko ti won se iwode e fopin si iko SARS, koni nilo pe enikankan ma so pe oun fe da duro…”

Bakan naa lo tun rọ gbogbo awọn ti ọrọ kan lati ranti ohun to sẹlẹ nigba ogun Biafra, ki wọn si maa se gbagbe orin orílẹ̀ èdè Nàíjíríà to sọ pe ..” ki’sẹ awọn akọni wa, ko maa se ja s’asan..” nigba ti o fi kun un pe, o soro lati kọ́lé sugbọn o rọrun lati da ilé wo.

O tun fi asiko naa ke si gbogbo awọn to n lọwọ ninu ijinigbe-fini-pawo ati awọn baba isalẹ wọn lati ranti àtubọtan, nigba ti o rọ gbogbo awọn oloselu lati gba alaafia laye ni pataki julọ bi wọn se n palemọ fun idibo ọdun 2023.

Saaju ninu oro ikinni kaabo re ni alaga egbe akoroyin niìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ọgbeni Ola Ajayi lu ọjọgbọn Olagoke lọgọ ẹnu fun awọn ipa ribiribi ti o n ko lawujọ, to si gbadura pe ki Eleduwa tubọ maa ran an lọwọ siwaju si.

Abiola Olowe
Ibadan.

Leave A Reply

Your email address will not be published.