Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó rọ ìjọba láti tètè dènà ìtànkálẹ̀ ìpéle kẹta àrùn COVID-19

Lanre Lagada Abayomi

0 193

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣ̀ofin Ìpínlẹ̀ Èkó ti rọ ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà àti ijọba Ipinlẹ Eko lati mojuto àwọn arìnrìn-àjò tó ń wọ orílẹ̀-èdè yìí láti le dènà ìtànkálẹ̀ ìpele kẹta àrùn COVID-19 lórílẹ̀-èdè yìí.

Aṣofin Rotimi Olowo lo mu aba yii wa ninu ijiroro Ile Aṣofin naa lori ipele tuntun arun COVID-19 yii. Aṣofin Olowo to jẹ alaga Igbimọ to n ri si Iṣuna-owo ninu Ile Aṣofin naa sọ pe Ijọba Apapọ ni lati maa mojuto awọn eniyan ti wọn n wọ ilu bayii, ki wọn si maa fi wọn sabẹ ayẹwo fun ọsẹ kan bi wọn ba ti de bayii, ki wọn si ri i daju pe wọn ṣe ayẹwo arun naa. O ni:

“Ijọba Ipinlẹ Eko ni lati bẹrẹ ipolongo ilanilọyẹ kaakiri nipa awọn ohun to yẹ ni ṣiṣe fun didaabo bo ara ẹni lọwọ arun COVID-19, bii lilo ibojubomu, fifọwọ deedee ati fifi aaye silẹ laarin ara ẹni loorekoore. Gomina Ipinlẹ Eko ni lati paṣẹ fun Alakoso-agba fun Eto Ilera lati jẹ ki awọn ara ilu lanfani si ayẹwo arun yii kaakiri ipinlẹ yii. Ki ikede ilanilọyẹ arun COVID-19 wa ni awọn ile-iwe, ṣọọṣi, moṣalaṣi, aarin ọja ati ile igbafẹ.”

Aṣofin Olowo fi kun akoonu aba naa pe o yẹ ki wọn gboriyin fun Gomina Babajide Sanwo-Olu fun akitiyan rẹ lati tete ta awọn ara ilu ji nipa ajakalẹ arun COVID-19 tuntun yii.

O fi kun un pe o yẹ ki ijọba ipinlẹ yii ni awọn ibi iṣiṣẹ ni awọn papakọ ofurufu orilẹ-ede yii lati ri daju pe awọn arinrinajo forukọ silẹ ni ipinlẹ yii, ki wọn si ri i daju pe wọn fi wọn sabẹ ayẹwo, ki wọn si mọ ile wọn.

Oludari Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa wa paṣẹ fun Akowe-agba Ile Aṣofin naa, Ọgbẹni Ọlalekan Ọnanẹkan lati kọ lẹta si Gomina Sanwo-Olu lori aba naa, nitori o ṣe e sẹ ki oogun abẹrẹ ajẹsara COVID-19 to wa nilẹ ma kawọ tuntun yii.

Aṣofin Ọbasa sọ pe ko bojumu ki wọn tun ti awọn eniyan mọle lode oni ti ọrọ-aje n mẹhẹ yii. Fun idi eyi, ki awọn ara ilu tete gbe igbesẹ didaabo itankalẹ arun yii.

Aṣofin Oluyinka Ogundimu sọ pe o ṣe pataki ki wọn maa ṣe ayẹwo fun awọn to ba ba ti irin-ajo de bayii, bakan naa ni Aṣofin Victor Akande sọ pe wọn gbọdọ tete fopin si itankalẹ arun yii.

Lara awọn aṣofin ti wọn tun fi ijiroro wọn ṣatilẹyin si aba yii ni Aṣofin AbiọdunTọbun, Aṣofin Adedamọla Richard ati Aṣofin Gbọlahan Yishawu.

Leave A Reply

Your email address will not be published.