Take a fresh look at your lifestyle.

COVID-19: Àwọn ènìyàn mẹ́tàlélọ́gọ́fà ni wọ́n ti ní àrùn Corona báyìí lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà

103

Àwọn ènìyàn mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123) ni wọ́n ti ní àrùn Corona, iyẹn , COVID-19 báyìí lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà , ní èyí tí ó jẹ́ kí  iye àwọn ènìyàn  tó ti ní àrun Covid 19 lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrún-le-ni-ọ̀kẹ́-mẹ̀jọ-le-ni-oókànlá-din-ni-ojì-lelọ́ọ̀dúnrún (169,329).

Ajọ to n  gbogun  ti ajakalẹ arun lorinlẹ ede Naijiria. The Nigeria Centre for Disease Control (NCDC) lo kede eyi lori itakun ẹrọ ayelujara wọn  ni owurọ ọjọ Aiku lọjọ kejidinlogun,osu keje, ọdun 2021.

Gẹgẹ bi ajọ naa se sọ pe ipinlẹ mẹjo ni wọn ti ri awọn to ni aarun ọhun, awọn ipinlẹ naa ni – Lagos (70), Akwa Ibom (18), Ogun (10), Oyo (8), Rivers (8), Ekiti (4), FCT (4), Bayelsa (1).”

Ajọ NCDC tun kede pe iye awọn eniyan ti wọn ti ni arun COVID-19 jẹ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrún-le-ni-ọ̀kẹ́-mẹ̀jọ-le-ni-oókànlá-din-ni-ojì-lelọ́ọ̀dúnrún (169,329). nigba ti iye awọn eniyan  to ti gba iwosan jẹ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàta-le-ni-ọ̀kẹ́-mẹ̀jọ-din-ni-mèjì-din-ni-ojì ( 164,672) nigba ti awọn eniyan  mẹ̀rin-din-ni-ojì-le-ni-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ọ̀kànlá (2,1262) ti padanu ẹ̀mí wọn.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.