Ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ètò okoòwò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà pe àkíyèsí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè sí ìlànà ààrùn covid-19 tó wà ní jákè-jádò orílẹ̀-èdè, bí wọ́n se ń sàjọyọ̀ ọdún iléyá (Eid-Al-Adha) tó ń bọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó wà láti àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NCDC) se sọ pé àwọn méta ní ìpínlẹ̀ Delta ni wọ́n ti kó ààrùn náà.
Wọ́n se àfihàn yii ní ìpàdé ìgbìmọ̀ tí wọ́n se, ní èyí tí ó jẹ́ ìpàdé mèjìdinniọgọ́fà (118) ní ọjọ́bọ̀ tí ó wáyé ní orí ẹ̀rọ ayélujára, tí igbákejì ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà, Ọjọgbọn Yemi Osinbanjọ tí ó darí ìpàdé náà, nígbà tí àwọn Gomina ìpínlè, àwọn Minisita, alakoso ile ifowopamọ apapọ ati awọn oṣiṣẹ ijọba miran naa si wa nibẹ pẹlu
ọjọgbọn Yemi Osinbanjọ wa rọ awọn gomina ipinlẹ lati tẹle awọn ilana pataki ti yoo dena omiyale ọdun 2021.
Damola and Kehinde