Ìgbìmọ̀ ìjọba àpapọ̀ ti fọwọ́sí bilionu mẹ́sàn án lé-lọ́ọ̀dúnrún láti fi ṣe ojú ọ̀nà ọkọ̀
Ìgbìmọ̀ ìjọba àpapọ̀ ti fọwọ́sí bilionu mẹ́sàn án lé-lọ́ọ̀dúnrún láti fi ṣe ojú ọ̀nà ọkọ̀ márosẹ̀ ti àwọn ìpínlẹ̀ Borno, Kaduna, Lagos and Ogun States.
Minisita fun eto isẹ oju popo ati ilé , Babatunde Fashola lo sọ eleyii fun awọn akọroyin ile aarẹ lẹyin ipade ti igbimọ ijọba apapọ se niluu Abuja, ni eyi ti aarẹ Muhammadu Buhari dari rẹ̀.
O tẹsiwaju pe ile-isẹ Dangote ni yoo maa kọ awọn opopona ọhun , ni eyi ti ijọba apapọ yoo lo owo tiwon ri gba nipa owó orí ti awọn ara ilu san.
Bakan naa, nibi ipade igbimọ ijọba apapọ to waye ọhun ni wọn ti bura awọn akọwe agba fun ile-isẹ ijọba apapọ wọnyi, Ibrahim Idris Yusuf lati ipinlẹ Katsina , Olusesan Adebiyi lati ipinlẹ Ekiti , Maryanne Ngozi Onwudiwe lati ipinlẹ Enugu , Marcus Olaniyi Ogunbiyi lati ipinlẹ Eko ati Ibrahim Abubakar Kana lati ipinlẹ Nasarawa .
Leave a Reply