Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbìmọ̀ ìjọba àpapọ̀ ti fọwọ́sí bilionu mẹ́sàn án lé-lọ́ọ̀dúnrún láti fi ṣe ojú ọ̀nà ọkọ̀

0 266

Ìgbìmọ̀ ìjọba àpapọ̀ ti fọwọ́sí bilionu mẹ́sàn án lé-lọ́ọ̀dúnrún láti fi ṣe ojú ọ̀nà ọkọ̀ márosẹ̀ ti àwọn  ìpínlẹ̀ Borno, Kaduna, Lagos and Ogun States.

Minisita fun eto isẹ oju popo  ati ilé , Babatunde Fashola lo sọ eleyii  fun awọn akọroyin ile aarẹ lẹyin ipade ti igbimọ ijọba apapọ se niluu Abuja, ni eyi ti aarẹ Muhammadu Buhari dari rẹ̀.

O tẹsiwaju pe  ile-isẹ Dangote ni yoo maa kọ awọn opopona ọhun , ni eyi ti ijọba apapọ yoo lo owo tiwon ri gba nipa owó orí  ti awọn ara ilu san.

 

Bakan naa, nibi ipade  igbimọ ijọba apapọ to waye  ọhun  ni wọn ti bura awọn akọwe agba fun ile-isẹ ijọba apapọ wọnyi,  Ibrahim Idris Yusuf lati ipinlẹ  Katsina , Olusesan Adebiyi lati ipinlẹ  Ekiti , Maryanne Ngozi Onwudiwe lati ipinlẹ  Enugu , Marcus Olaniyi Ogunbiyi  lati ipinlẹ Eko ati  Ibrahim Abubakar Kana lati ipinlẹ  Nasarawa .

Leave A Reply

Your email address will not be published.