Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì ààrẹ Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀sínbàjò darí àpèjọ àwọn ìgbìmọ̀ àjọ tó ń rísí ìṣòwò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 124

Igbákejì ààrẹ orílẹ̀-èdè, ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀sínbàjò ń darí ìpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ àjọ tó ń rísí ìṣòwò[NEC] lórí ayélujára,ìpàdé náà bẹ̀rẹ̀ ní agogo mọ́kànlá àárọ̀, ní ọjọ́ ọjọ́bọ̀.

Gbogbo gomina mẹrin-din-logoji ni o n kopa nibi ipade naa lori ayelujara.

Nibi ipade rẹ ni Oṣu Karun, Igbimọ naa pinnu lati pe apejọ pataki kan lati ṣe atunyẹwo awọn esi igbimọ  to n  ṣewadii idajọ ti wọn da silẹ jakejado orilẹ-ede Naijiria, lati ṣe iwadi ifẹhonuhan  EndSARS ti o waye ni orilẹ-ede, ni ọdun to kọja.

Wọn tun le jiroro lori  bi wọn o tun ṣe ṣe ipade pataki  igbimọ naa risi nibi apejọ ọjọbọ.

Awọn ọrọ miiran ti o tun le jẹyọ ninu ipade naa ni,abẹrẹ ajesara COVID-19 ti nlọ lọwọ ati eto ọrọ aje.

Itẹsiwaju alaye nigbamii.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.