Take a fresh look at your lifestyle.
Adha

Tí irin bá karin, ọ̀kan á tẹ̀, ikọ̀ ọmọ ogun Nàíjíríà gbéná kojú ikò ọlọ̀tẹ̀ ESN

100

Ikò ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàíjíríà  tí wọ́n kó lọ sí agbègbè  Adani  ní ìjoba ìbílẹ̀  Uzo-Uwani tó wà ní ipinlẹ  Enugu State, ni wọ́n ti gbéná kojú ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀  Eastern Security Network (ESN) lásìkò tí ikọ̀ ọmọ  ogun méjéèjì pàdé ní  Iggah/Asaba .

Gẹgẹ bi alukoro ile-isẹ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria , ọgagun  Onyeam Nwachukwu,se sọ pe  ija to waye laarin ikọ mejeeji naa ti gbẹmi eniyan meji lara ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria.Amọsa ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria , ko ni kaarẹ lati ri i pe wọn gbogun ti ikọ ọmọ  ọlọtẹ ESN .

Ile-isẹ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria, wa fi ọkan  gbogbo ọmọ  orilẹ ede  Naijiria balẹ  pw awọn yoo  tubọ maa pese eto aabo to peye fun tẹru-tọmọ lorilẹ ede yii, nipa fifọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro ati ajọ eleto aabo miran.

Ile-isẹ ọmọ ogun orilẹ ede yii tun wa rọ gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria lati tubọ fọwọsowọpọ pẹlu awọn ile-isẹ eleto aabo ati awọn agbofinro nipa titẹle ofin , ki wọn si wa maa fi to awọn ajọ eleto aabo leti ti wọn ba ti gburo ikọ ọlọte tabi awọn eniyan ti irin wọn ba mu ifurasi lọwọ.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.