Take a fresh look at your lifestyle.
Adha

COVID-19: Gómìnà Ìpínlè Delta mú ààbò abẹ́rẹ́ àjẹsára dá àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

28

Gómìnà  Ìpínlè Delta, Ifeanyi Okowa ti fi ààbò abẹ́rẹ́ ajesara AstraZeneca àti gbogbo àwọn abéré àjesára mìíràn, tí wọ́n ń lò fún ìdènà àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 dá àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú.

Senator Okowa n ba awọn oniroyin sọrọ ni ọjọ iṣẹgun lẹyin ipade ikọkọ pẹlu Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo ni Ile ijọba, ni ilu Abuja.

Okowa, ẹniti o dari ikọ igbimọ  to n risi Iṣowo ni Orilẹ-ede  pẹlu ajọṣepọ Igbimọ alatọsọna aarẹ  lori COVID-19, sọ pe, awọn ajesara yii ko lewu, o fi kun pe ikọlu ipa ti o wa lẹyin  abere ajesara ọhun si  jẹ iwonba ranpẹ.

“Ko ti si iroyin iku kankan lẹyin abẹrẹ ajesara ọhun, gbogbo wa la si ti gbaa;  alakọkọ ati ikeji ati pe kampe lawa, ”Okowa, ti o tun jẹ dokita iṣoogun lo sọ bẹ.

 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.