Take a fresh look at your lifestyle.

Ààbò Orílẹ̀-èdè: Àwọn ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin pè fún àfikún owó láti pèsè ààbò tópéye

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

23

Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin Orílẹ̀-èdè ń bèèrè fún  owó  tó jọjú  díẹ̀ síi, fún Àwọn ọmọ-ogun Nàìjíríà àti àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò míràn, láti le kojú ewu  rògbòdìyàn tí ó ń da orílẹ̀-èdè náà láàmú.

Abẹnugan ile, Ahmed Lawan pe ipe naa ni  ọjọ iṣẹgun, ni ibi  apejẹ ounjẹ alẹ kan ti aarẹ Muhammadu Buhari pe, fun gbogbo awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ati Awọn ọmọ ile Igbimọ Aṣoju.

O tẹnumọ iwulo afikun  owo diẹ sii fun aabo,   ti si pe akiyesi si pe, “ko si idokowo ti o dara julọ ni orilẹ-ede Naijiria loni ju idokowo lori eto  aabo,”pẹlu ireti pe owo  aabo yoo gberu  diẹ sii ni isuna 2022.

Abẹnugan sọ pe ounjẹ alẹ ọhun kiiṣe ohunjẹ jijẹ bikoṣe igbiyanju  lati mu awọn ikọ ijọba lati jọ  ṣiṣẹ ni pẹkinpẹki.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.