Take a fresh look at your lifestyle.

tí irin bá karin, ọ̀kan á tẹ̀, ikọ̀ ọmọ ogun Nàíjíríà dáńa sun ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀, niwọ́n bá júbà ehoro

175

Ikọ̀ ọmọ ogun àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, ti ọwọ̀  Hadin Kai ti gbánáyá ikọ ọmọ  ọgun ọlọtẹ̀, tí wọ́n sì tún mú ọkùnrin tó ń se agbódegbà fún wọn ní ìlú Katarko tó wà ní ìpínlẹ̀  Yobe , sé tí ikú ilé kò bá pani, tòde kò leè pani.

Ninu atẹjade kan  ti adari ẹka to n mojuto ibasepọ fun ile-isẹ ọmọ ogun orilẹ ede yii , ọgagun, Onyeama Nwachukwu lo sọrọ yii lasiko to n se afihan ọkunrin ọ̀dàlẹ̀ to n se agbódegbà fun ikọ ọmọ ogun ọlọte , ti orukọ rẹ n jẹ,Abor Kawu, ni eyi ti o jẹwọ pe oun ni o  maa n sọ awọn asiri  ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria fun ikọ ikọ ọmọ ogun ọlọtẹ.

Adari ile-isẹ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria, ọgagun  Faruk Yahaya  wa gbosuba fun gudugudu meje. yaya mẹfa ti ikọ ọmọ ogun Naijiria se, o wa tun rọ̀ wọn lati tubo rii i pe wọn gba gbogbo ikọ̀ ọlọtẹ, Boko Haram/ISWAP kuro patapata ni orilẹ ede Naijiria.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.