Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ òsèlú PDP nilẹ Gusu: Makinde tẹ́wọ́gba àbájáde ìgbìmọ̀ ẹlẹ́nu márùn ún

93

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde,  ti tẹwọgba abajade  igbimọ ẹlẹnu marun un ti gomina tẹlẹri fun ipinlẹ Ọsun ,Olagunsoye Oyinlola dari rẹ, lati yanju wahala ati isoro to n koju ẹgbẹ oselu, People’s Democratic Party (PDP) ni ila Gusu orilẹ ede Naijiria.

lasiko ti gomina Makinde, ń tẹwọgba abajade iroyin naa lọjọBọ , o ni  abajade yii wulo pupọ ki ẹgbẹ oselu PDP lee wa ni ọkan, kii se fun ẹkun Gusu nikan bi ki i se fun  gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ  oselu PDP  to wa lorilẹ ede Naijiria.

O wa dupẹ lọwọ igbimọ ọhun fun isẹ takun-takun ti wọn se , o ni awọn abajade to  wa ninu iwe naa, ni ẹgbẹ oselu PDP yoo mulo , ki ilọsiwaju lee ba ẹgbẹ oselu PDP lorilẹ ede Naijiria lapapọ.

Makinde tẹsiwaju pe: “ Orilẹ ede Naijiria nilo ọkunrin ati obinrin ti wọn ni ẹri ọkan , ti wọn ni ironu lati mu idagbasoke ba orilẹ ede Naijiria .Idi niyi ti awọn gomina to wa ni ila Gusu orilẹ ede Naijiria se ipade lati fimọsọkan laifi ti ẹgbẹ ọtọtọ ti wọn wa se, ti wọn si gbe igbesẹ lati se ohun ti yoo mu inu awọn eniyan wọn dun , lati ri i pe idajọ ododo wa, ti ko si ni si iwa aparo kan ,  ga ju ọkàn lọ..”

Gomina wa salaye pe oun yoo mu iroyin naa fi sọwọ si igbimọ to n sakoso ẹkun ti ẹgbẹ oselu ọhun.

Oyinlola  wa dupẹ lọwọ gomian Makinde fun iranlọwọ  to se fun igbimọ ọhun lati se aseyọri ninu iyanju wọn lọna ati wa ojutuu si isoro ati wahala to n koju ẹgbẹ oselu PDP ni ila Gusu orilẹ ede Naijiria.

o wa rọ gomina ati awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun lati samulo awọn ohun ti wọn kọ sinu iwe naa nitori pe yoo se wọn ni anfaani pupọ lati jẹ ki ẹgbe naa wa ni ipo to dara paapaa julọ ni ila Gusu orilẹ ede Naijiria.

Lara awọn to wa ninu igbimọ ọhun ni , ọmọba Oyinlola [alága ], asofin Olayinka Kukoyi [akọwe], oloye  Saka Balogun ati  Omolade Oluwateru.

Leave A Reply

Your email address will not be published.