Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ ọmọ ọgun tí wọ́n farapa yóò gba ìtọ́jú tó péye: Adarí ilé-isẹ́ ológun

Ademọla Adepọju

0 263

Adarí ilé-isẹ́ ológun, Ọgagun Faruk Yahaya  ti sọ fún ikọ̀ ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n farapa pé wọn yóò rí ìtọ́jú tó péye ní ilé ìwòsàn áwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà ní Ìpínlẹ̀ Kaduna.

Gẹ́gẹ́ bí adarí ẹ̀ka tó ń mójútó ìbásepọ̀, fún ilé-isẹ́ ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọgagun Onyeam Nwachukwu, se sọ, ó ní Faruk sọ ọ̀rọ̀ náà ní ọjọ́ kẹjọ, osù kẹrin, ọdún 2021. Nígbà tí ó lo bẹ àwọn tí wọ́n farapa wò ní ilé wòsàn.

Ọgagun Faruk tún sọ pé àwọn ti se gbogbo ètò tí ó yẹ fún àwọn tí wọ́n nílò ìtọ́jú ní òkè òkun, paapa jùlo àwọn tí wọ́n nílò láti se isẹ́ abẹ.

Ó tún tẹ̀síwájú pé àwọn ètò ń lọ lọ́wọ́ láti kọ́ ilé ìwòsàn tí wọ́n yóò tí máà se àyèwò ara. bakan náà ni wọ́n tun maa se agbederọ ẹya ara  fun awọn ti wọn padanu ẹya ara wọn lẹnu isẹ wọn fun orilẹ-ede.

 

 

 

 

Hamzat Roshidat

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button