Take a fresh look at your lifestyle.

Adarí ilé-isẹ́ ológun bèèrè ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn tó ń pèsè ètò ààbò.

Ademọla Adepọju

118

Adarí ilé-isẹ́ ológun ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (COAS), Ogagun Faruk Yahaya ti bèèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àjọ eleto ààbò lórílẹ̀-èdè.

Ó sọrọ yii lasiko tí ó lọ sí ibi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde àwọn  eniyan mẹ́tàlélógójì ti ilé-ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ ogun tó ń mójútó ohun ìjà ogun lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà se ayẹyẹ fun ní agbègbè Jaji, Ìpínlè Kaduna.

Nígbà tí ó ń sàyẹ̀wò lórí ilé-èkọ́ imo erọ igbalode àti àwọn isẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ ní ilé-isẹ́ ológun ọhun, Ogagun Faruk  salaye  lórí àwọn ànfààní tó wà lóri imọ ẹkọ ile-ẹkọ naa.

Ó sì tún sọ àwọn àseyọrí ti àwọn ikọ ọmọ ogun ti se sẹ́yìn lórí ẹjọ́ ọ̀daràn, ọlọ́tẹ̀, apànìyàn àti àwọn ajínigbé lórílẹ̀-èdè Naijiria.

 

 

 

 

Hamzat Roshidat

Leave A Reply

Your email address will not be published.