Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní dandan jẹ́mánì gbọ́dọ̀ dá gbogbo àwọn nkàn ìṣẹ̀ǹbáyé tí wọ́n tí gbẹ́sẹ̀ lé padà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

242

Ìjọba Nàìjíríà ti bèèrè fún ìdápadà gbogbo àwọn  ojì-din-lẹwá le ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́fà Idẹ  ti ilu Benin tí wọ́n  gbẹ́sẹ̀ lé  ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà ní ọdún 19th, tí wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di   ilé-ìṣọ́ Jẹ́mánì.

Minisita fun iroyin ati Aṣa, Alhaji Lai Mohammed lo beere fun eyi ni ilu Balin,Jẹ́mánì, ni  Ọjọbọ, lakoko ti o n ṣe  ipade lọtọọtọ pẹlu Minisita fun Ipinle fun Aṣa, Ọjọgbọn Monika Grutters ati Minisita okeere ti Jẹmánì, Ọgbẹni Heiko Maas.

Ni idahun si ibeere yii ,  Ọjọgbọn Grutters sọ pe, Jẹ́mánì ti ṣetan lati ṣe ‘ipadabọ to lami’  awọn  ohun iṣẹnbaye ti wọn ti gbẹsẹle ọhun, Alhaji Mohammed, ti o dari aṣoju Naijiria si awọn ijiroro naa, sọ pe gbogbo rẹ ni wọn gbọdọ da pada, kii ṣe  diẹ ninu awọn nnkan ọhun.

O tun sọ pe ọrọ  imudaniloju ko yẹ ki o jẹ wahala rara,ni eyiti o ni lati ṣe pẹlu ibiti   awọn ohun iṣẹnbaye naa ti wa, ko yẹ ki iyẹn da ati da pada duro rara,o sọ ni afifi kun:tori pe o jẹ  idẹ Benin ti jẹ ki a mọ orisun wọn,ti  Benin si jẹ ọkan ninu awọn ilu ni orilẹ-ede Naijiria.

O sọ pe ijiroro ti n lọ lọwọ laarin Naijiria ati Jẹmánì lori bi wọn yoo se da awọn ohun iṣẹnbaye naa pada ,  ati bi  ibaṣepọ ti o gbooro, yoo se tubọ fẹsẹ mulẹ sii laarin orilẹ ede mejeeji .

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.