Ilé-iṣẹ́ àwọn ọmọ ogun òfurufú kégbàjarì :’ẹ ṣọ́ra fún ayédèrú ìròyìn gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílé ẹ̀kọ́ nọ́ọ̀sì ọmọ ogun òfurufú
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Oludari Ilé-iṣẹ́ àwọn ọmọ ogun òfurufú (NAF), ti ya ara rẹ̀ kúrò nínú ìkéde tí wọ́n ń pín kiri lórí àwọn ẹ̀rọ ayélujára kan nípa bíbẹ̀rẹ̀ sí ní gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Nọ́ọ́sì, NAFCON.
NAF tọka si ikede yii bi irọ ati arekereke, eyi ti ko wa lati ọdọ NAF.
Alakoso oludari Ibaraẹniṣepọ ati iroyin , NAF, Air Commodore Edward Gabkwet sọ pe, alakoso ile-ẹkọ ọhun si “abala ND / HND” ti NAF fun imọ ẹkọ Nọọsi (NAFCON)ọhun,dari awọn oludije ti ko mọ pe irọ ni gbogbo rẹ bade, lati san ẹgbẹrun mẹẹdogun abọ Naira owo, ti ko ni isanpada si “Ọfiisi alakoso ọhun”.
Gabkwet ṣalaye pe, lati ṣe ijamba yii , awọn onijibiti naa tun pese awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ alagbeeka ati ikansi ẹrọ ayelujara .
Leave a Reply