Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó fọwọ́sí àbádòfin tó fòfin de ṣíṣe àfihàn àwọn afurasí ọ̀daràn níwájú àwọn oníròyìn.

Lanre Lagada-Abayomi

0 360

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti fọwọ si apa kan ofin to nii ṣe pẹlu iwa ọdaran ipinlẹ yii, eyi to fofin de ṣiṣe afihan awọn afurasi ọdaran niwaju awọn oniroyin.

Abadofin naa ni wọn fọwọ si ninu ijiroro wọn, eyi ti Igbakeji Oludari Ile Aṣofin naa, Aṣofin Ẹshinlokun-Sanni, eni ti o ṣoju fun Oludari Ile naa, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, dari.

Ipele kesan-an (abala A) abadofin naa fofin de ọlọpaa lati fi oju ọdaran ti wọn fẹsun kan han niwaju awọn oniroyin.

Abadofin naa tun sọ pe ohun kan ṣoṣo ti o le mu ọlọpaa fọwọ ofin mu eniyan laimu aṣẹ lati ile-ẹjọ dani ni pe, wọn fura pe afurasi naa ni ohun ija ogun ti o le fi ṣọṣẹ lọwọ. Abala ofin naa tun fofin de ọlọpaa lati fọwọ ofin mu ẹlomiiran lorukọ afurasi ọdaran kan.

Abala ofin naa tun fi mulẹ pe awọn ọlọpaa gbọdọ ḅọwọ fun ẹtọ ọmọluabi ẹnikọọkan, wọn ko gbọdọ maa ṣe afurasi niṣekuṣe tabi fi iya jẹ ẹ lọna aitọ ko to di ọjọ ti wọn yoo gbe e lọ sile ẹjọ tabi ki wọn fi ọdaran kan silẹ lai tẹle ofin yii tabi ofin to wa nilẹ.

Lẹyin ti wọn ti fohun ṣọkan lati sọ abadofin naa di ofin, Igbakeji Oludari Ile Aṣofin naa paṣẹ fun Adele Akowe-agba Ile Aṣofin naa, Ọgbẹni Ọlalekan Ọnafẹkọ lati fi abadofin naa ṣọwọ si Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinlẹ Eko lati fọwọ si i, ko le di ofin amulo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button