Take a fresh look at your lifestyle.

Ètò ààbò : Ìjọba Ṣàgbékalẹ̀ Ilé-iṣẹ́ Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pàjáwìrì Ní ìpínlẹ̀ Zamfara

40

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ti sàgbékalẹ̀  ẹkà Ilé-iṣẹ́ Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pàjáwìrì( Emergency Communications Centre,ECC ) ní ìpínlẹ̀  Zamfara , tí ó jẹ́ ìlà òòrùn orílẹ̀ èdè Nàíjíríà láti gbógun ti wàhálà tí ìpínlẹ̀ náà ń dojúkọ lórí ètò ààbò.

Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati lilo ẹrọ ayelujara fun okoowo, ọmọwe Isa Pantami lo sọ eyi lasiko ti o gba gomina ipinlẹ Zamfara ,Muhammad Bello Matawalle ni alejo ni ọfiisi rẹ to wa niluu  Abuja.

Agbẹnusọ fun minisita naa, iyaafin  Uwa Suleiman lo sọ eyi ninu atẹjade kan ti Pantami kọ pe, minisita seleri lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn gomina to wa lorilẹ ede Naijiria lati pese isẹ lọpọ janturu lọna ati gbogun ti wahala eto aabo to n dojukọ orilẹ ede  Naijiria.

Gomina Matawalle  wa gbosuba fun minisita fun eto ibaraẹnisọrọ lori ipa pataki ti o n ko ni ipinlẹ rẹ lati ri i pe awọn eniyan to n gbe ni igberiko n jẹ anfaani erọ ibaraẹnisọrọ.

O tun wa rọ minisita lati tubọ pese awọn ẹka ibaraẹnisọrọ  , ni eyi lati tubọ pese isẹ́ fun awọn ọ̀dọ́.

Eto pipese ẹka ile -isẹ ibaraẹnisọrọ  pajawiri  ti ijọba se fun awọn ipinlẹ  ni lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ati lati gbogun ti eto aabo to mẹhẹ ni awọn ipinlẹ to wa lorilẹ ede Naijiria.

Lara awọn ile-isẹ ati ajọ to ti jẹ anfaani ẹka eto ibaraẹnisọrọ  pajawiri nipa pipese ẹrọ ibaraẹnisọrọ 112 ni  ile-isẹ awọn ọlọpaa ,ile-isẹ to n mojuto eto oju ọna popo, ile-isẹ eto aabo ara  ẹni, ni aabo ilu,ile-isẹ pana-pana, ile-isẹ to n mojuto eto isẹlẹ pajawiri.

Ni bayii, ẹka eto ibaraẹnisọrọ pajawiri ti wa ni ipinlẹ mọkandinlogun to wa lorilẹ ede Naijiria ati ilu  (FCT), Abuja.

Leave A Reply

Your email address will not be published.