Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin Nàíjíríà àti Ghana yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ lórí ètò òfin ọrọ̀ ajé

0 160

ilé ìgbìmọ̀ asojú -sòfin orílẹ̀ èdè Nàíjíríà àti orílẹ̀ èdè  Ghana ti fẹnukò lórí òfin tí ilé ìgbìmọ̀ asojú -sòfin méjéèjì yóò máa lò láti leè tẹpẹlẹ mọ́ ìbásepọ̀ àwọn méjéèjì pàápàá jùlọ lórí ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè méjéèjì.

Oludari ile igbimọ asoju , ọgbẹni Femi Gbajabiamila sọrọ yii niluu Abuja lasiko ipade ti o se pẹlu oludari  ile igbimọ asoju orilẹ ede Ghana,Alban Sumana-Bagbin.

Ọgbẹni Gbajabiamila salaye nipa wahala lori eto ọrọ̀ ajé to maa n sẹlẹ laarin orilẹ ede  Ghana ati orilẹ ede Naijiria , ni eyi ti orilẹ ede mejeeji naa sẹsẹ yanju.

Ọgbẹni  Alban Sumana-Bagbin ni  ibasepọ to wa laarin orilẹ ede Naijiria ati orilẹ ede Ghana ti wa lati ọjọ to ti pẹ́, o ni awọn abadofin ti orilẹ ede mejeeji naa  fọwọsi yoo tun jẹ ki ibasepọ to wa laarin orilẹ ede mejeeji naa tun fẹsẹ mulẹ sii.

Oludari ile igbimọ asofin ti orilẹ ede  Ghana wá rán ile igbimọ asofin si ijọba   orilẹ ede Naijiria lati satunse lori awọn ofin ti wọn fi tako kiko  awọn ọja ti o ba wa lati  orilẹ ede Ghana wa si orilẹ ede Naijiria.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.