Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ ọ̀fẹ́ ní ìpínlẹ̀ Borno

Ademọla Adepọju

0 95

Àjọ tó ń mójútó ètò ọmọnìyàn, àjálù àti ìdàgbàsókè àwùjọ pẹ̀lú àjọs̀epọ̀ ìjoba ìpínlẹ̀ Borno ti bẹ̀rẹ̀ láti máa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní oúnjẹ ọ̀fẹ́.

.Eto ounje ọfẹ yii waye lati pese ounjẹ afara-loore fun awon ọmo ile-iwe alakọọbẹrẹ lati kilaasi kinni sí kilaasi kẹta (primary 1 to 3) ni gbogbo ipinlẹ to wa lorilẹ ede Naijiria.

Oludari ẹka to n mojuto bí isẹ se n lọ nipa ounjẹ ọfẹ ,Ali Grema  lo sọro yii lasiko to n soju fun Minisita fun àjọ tó ń mójútó ètò ọmọnìyàn, àjálù àti ìdàgbàsókè àwùjọ lorilẹ ede Naijiria, Sadiya Umar Farouq  ni ipinlẹ Borno. 

O tẹsiwaju pe“ Gbogbo awọn akẹkọọ lati kilaasi kinni si kilaasi kẹta  ti wọn wa ni ile-ẹkọ ti ijọba ni ounjẹ ọfẹ yii wa fun , lai bikita fun idile ti wọn ti jade wa. Gbogbo awọn oludari ile -ẹkọ alakọbẹrẹ ati awọn to n dáná fun wọn ati awon obi wọn ni awon yoo forukọ ati aworan wọn  silẹ lati lee mojuto ọunjẹ naa.

Ọjọgbọn Isa Hussain Marte , to jẹ oludari awọn osisẹ fun gomina ipinlẹ Borno , ọjọgbọn Babagana Umara Zulum  naa tun sọ pe ifilọlẹ ounjẹ ofẹ fun awọn akẹkọọ ọhun yoo tun ran eto ẹkọ lọwọ lati tun ni idagbasoke ni ipinlẹ ọhun.O tun tẹsiwaju pe

” Eto ẹkọ ni ohun ti ijọba ipinlẹ Borno mu lọkununkundun julọ.Ohun si ni yoo maa jẹ akọkọ ninu ipinnu ijọba rẹ”.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.