Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀yin agbófinró , ẹ gba gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé padà-Buhari

40
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Muhammadu Buhari ti pàsẹ fún gbogbo àwọn agbófinro àti àjọ elétò ààbò láti  rí i pé wọ́n gba gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn ajínigbé gbé sálo ní àwọn ìpínlẹ̀ Kaduna àti  Niger láìfarapa.
Aarẹ wa ni bo tilẹ jẹ pe iyanju n lọ lọwọ lati ri i pe wọn tun ko awọn agbofinro ati ikọ eleto aabo  lọ si  awọn ipinlẹ ti awọn ọdaran ti n se ọsẹ́ , bakan naa ni aarẹ Buhari tun wa rọ awọn agbofinro lati se isẹ́ wọn bi isẹ́  nipa gbigba awọn akẹkọọ ti wọn jigbe lọ ni awọn ipinlẹ ọhun.
Aarẹ Buhari wa rọ awọn gomina ipinlẹ lati tẹlẹ ilana ajọ agbaye nipa sise atilẹyin fun eto ile-iwe ati lati mojuto eto aabo awọn akẹkọọ.
Aarẹ wa ni iwa ọ̀lẹ, ọdaran ni awọn ajinigbe naa n hu, nipa kiko awọn ẹbi ati orilẹ sinu wahala .

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.