Take a fresh look at your lifestyle.

E yé fọ́ ọ̀pá epo rọ̀bì,ọgọ́ta biliọnu ní ìjọba àpapọ̀ máa ń ná láti tún un se lọ́dọọdún -Lai

Ademọla Adepọju

45

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ti ní ọgọ́ta biliọnu ni ijọba maa n na lati fi tun ọpa epo rọbi ati gaasi  ti awọn ọdaran kan maa n fọ́ ní ẹkun NIger/ Delta se .

Minisita fun eto asa ati iroyin lorilẹ ede Naijiria, lo sọrọ yii niluu  Abuja  lasiko ipade ijiroro laarin awọn ara ilu ati ijọba lori ọna ati daabo bo awọn ọpa epo rọbi ati gaasi , ipade yii  lo jẹ  ogún rẹ, ti yoo waye.

Minisita ni , bi ijọba se n gbiyanju lati maa pese awọn ohun amayedẹrun  bẹẹ ni awọn kan si n gbọmiran si wọn si n ba awọn ohun amayedẹrun yii jẹ.Nitori naa, ijọba yoo sa gbogbo ipa rẹ lati fopin si iru iwa ibajẹ bayii.

Minisita tun tẹsiwaju pe laarinosu kinni ni ọdun 2019n si osu kẹsnan ọdun 2020 , o ti le ni ẹgbẹrun   ọpa epo rọbi ati gaasi ti wọn ti bajẹ.

Lai  ni lati igba ti ijọba aarẹ Muhammadu Buhari ti de orí aleefalọdun 2015 ni o ti mu idagbasoe awọn ohun amayedẹrun ni ọkunukundun  lati lee mu itẹsiwaju ati idagbasoke ba eto ọọ̀ aje lorilẹ ede Naijiria.

 

Minisita tun sọ pe , o yẹ ki awọn ara ilu mọ pe dukia ijọba jẹ ti ara ilu, nitori naa, ti ẹnikankan ba n ba dukia ijọba jẹ, dukia rẹ lo n bajẹ .Idi niyi ti gbogbo awọn ara ilu gbọdọ maa daabo bo dukia ijọba.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.