Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Gáḿbíà fìmọ̀ ṣọ̀kan láti kojú àwọn ọlọ̀tẹ̀.

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

34

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Gáḿbíà ti buwọ́ lu ìwé àdéhùn lórí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ọmọ ogun láti kojúu àwọn ọ̀daràn tó ń da orílẹ̀ èdè wọn láàmú.

Oludamọran pataki si Minisita fun Aabo, Mohammed Abdulkadri, ninu ọrọ rẹ kan, pe akiyesi pe, wọn ni lati koju awọn irokẹkẹ ewu naa lapapọ.

Abdulkadiri ninu alaye naa sọ pe, Minisita fun Aabo Maj Gen Bashir Magashi ati Alakoso agba ti Gambia si Naijiria, Mohamadou Musa Njie, ni awọn oniduro fun awọn orilẹ-ede mejeeji.

Magashi sọ pe iwe adehun yii wa lasiko to dara julọ,paapaa lasiko  ti awọn ọlọtẹ n koju wọn.

Awọn aṣoju  orilẹ-ede mejeeji ṣe ileri ninu awọn ọrọ  wọn lọtọọ, lati tẹle gbogbo ilana iwe adehun naa.

 

 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.