COAS – Àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mú ìṣòkan lọ́kùúnkúndùn láti gbógun ti ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ọ̀gá àgbà fúnilé isẹ àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà (COAS) ,Ọ̀gágun àgbà Faruk Yahaya àti àwọn ọmọ- ikọ̀ rẹ̀ ,ní Mongadishu Cantonment ní ilé ìjọ́sìn kátólíkì ní Àbújá, ṣàfihàn àwọn ọmọ-ogun Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣọ̀kan lónírúurú àti lẹ́nu isẹ́.
Eleyii ni igba akọkọ ti ọgagun agba fun ile-isẹ́ ọmọ ogun ọhun, ti o jẹ Musulumi yoo darapọmọ awọn akẹgbẹ rẹ ti o jẹ Kirisitiẹni gẹgẹ bii ayẹyẹ isami ọdun ile-isẹ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria ti ọdun 2021.
COAS tọka si pe ohun n ṣe eyi nitori pe,ohun fẹ ki awọn eniyan mọ pe ologun n ṣiṣẹ gẹgẹ bii ẹyọkan ni.
ọga agba fun ẹka iṣẹ́ awọn ọmọ ogun,ọgagun agba AB Omozoje,nigbati o n fi imoore ẹ han, dupẹ lọwọ ọlọrun,ọgagun agba, fun atilẹyin rẹ si ologun ati si ọga agba fun eto Aabo ti ọga ajagun Elvis Njoku ṣe aṣoju rẹ nibi ayẹyẹ naa.
Leave a Reply