Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Eko dábàá ṣíṣe ìdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ fáfitì méjì

Lanre Lagada-Abayọmi

0 289

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti jiroro lori abadofin meji ti yoo ṣe idasilẹ ile ẹkọ giga meji ni ipinlẹ yii. Eyi ni Ifafiti Imọ eto Ekọ ati Ifafiti fun Imọ-ẹrọ.

Awọn abadofin mejeeji ti wọn gba wọle ni igba keji ninu gbagede Ile Aṣofin Eko ninu ijiroro ti Agbẹnusọ Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa dari ni wọn fa le igbịmọ to n moju to ọrọ Eto Ẹkọ ninu Ile Igbimọ Aṣofin yii (ti Ile Ẹkọ Giga) lọwọ, ki wọn si jabọ pada fun ile laarin ọsẹ meji.

Ninu ọrọ rẹ, Aṣofin Bisi Yusuff sọ pe abadofin ṣiṣe idasile fafiti imọ Eto-ẹkọ ni Ipinlẹ Eko, iyẹn University of Education, Lagos (UNEDLAG) yii dara, ati pe ki wọn fun awọn eniyan lanfani lati faaye silẹ fun ẹkọ igbawọle fun gbigba oye kinni ninu imọ ẹkọ kan (pre-degree). O ni abadofin yii yoo pese bi awọn to ba jade ni awọn ile-iwe yii yoo le fi tete waṣẹ ṣe funra wọn, pẹlu imọ iṣẹ ọwọ ti wọn ba pese fun ile ẹkọ bayii.

Aṣofin Sani Ọkanlawọ, Alaga igbịmọ to n moju to ọrọ Eto Ẹkọ ninu Ile Igbimọ Aṣofin yii sọ pe o ṣe pataki lati sọ Ile-ẹkọ olukọni Adeniran Ogunsanya ati ti Micheal Ọtẹdọla di ile-ẹkọ fafiti. O ni: “niwọn to jẹ pe aye o gba iwe-ẹri olukọni onipele kekere mọ, ọpọ awọn akẹkọọ ko si mu awọn ile-ẹkọ yii fun aayo akọkọ wọn fun idanwo atiwọle ile-ẹkọ giga orilẹ-ede yii, iyen, UTME. Bi a ba ṣe idasilẹ awọn ifafiti tuntun yii, yoo jẹ ki awọn akẹ̣kọọ to n lakaka lati wọle si fafiti Ipinlẹ Eko, iyẹn LASU din ku.”

Aṣofin Setonji David fara mọ abadofin yii, pe eleyii yoo le fopin si ipenija bi adinku ṣe n ba awọn olukọ ti wọn ri lo ni awọn ile-iwe alakọọbẹrẹ ati girama.

Aṣiwaju ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju ninu Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Sanai Agunbiade fi mulẹ pe abadofin naa dara, ati pe akẹkọọ gboye ile-ẹkọ olukọni Adeniran Ogunsanya loun naa, ti oun si ṣe iṣẹ olukọ fun ọdun marun-un pẹlu iwe-ẹri toun gba ni ile-ẹkọ yii

Aṣofin Abiọdun Tọbun naa fara mọ abadofin yii pe yoo le pese ọpọ olukọ bi wọn ba sọ ọ di ofin.

Ni ti idasilẹ ilẹ-ẹkọ fafiti Imọ-ẹrọ, awọn aṣofin naa gbagbọ pe igbesẹ naa yoo le pese awọn oṣiṣẹ akọṣẹmọṣẹ fun idagbasoke ipinlẹ yii.

Ninu aba tirẹ, Aṣofin Rauf Age-Sulaiman sọ pe ki wọn ma ṣe jẹ ki ẹkọ nipa awọn imọ to nii ṣe pẹlu ibagbe-ẹda ati ofin wa ni iru ile-ẹkọ fafiti imọ-ẹrọ bayii, nigba ti Aṣofin Fẹmi Saheed so pe iru imọ sayẹnsi ati tẹrọ bayii dara fun idagbasoke ilu.

Aṣofin Bisi Yusuff dabaa pe iru awọn imọ ẹkọ ti wọn yoo ba kọ ni iru ile-ẹkọ yii gbọdọ tẹle aṣa awọn eniyan, ki wọn si kẹkọọ to jẹ mọ iṣẹ agbẹ, ti yoo ṣadinku ọwọn gogo ounjẹ ni ipinlẹ yii

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button