Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Eko kìlọ̀ fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láti má ṣe dá àwọn oníkẹ̀kẹ́ alupùpù láàmú

Lanre Lagada-Abayọmi

0 302

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti paṣẹ fun awọn ijọba ibilẹ ati agbegbe idagbasoke ijọba ibilẹ lati jawọ ninu iwa gbigba owo aitọ lọwọ awọn onikẹkẹ alupupu ti wọn fi n jiṣẹ nibi kan si ibomiran, tabi maa da wọn laamu.

Eleyii lo waye nigba ti Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko. Aṣofin Mudashiru Ọbasa n tẹnu mọ ọn pe awọn ijọba ibilẹ yii ko lẹtọ lati maa gba owo-ori kankan lọwọ awọn ọnikẹkẹ alupupu ifiṣẹran yii. O ni kikida fifi-orukọ-silẹ awọn kẹkẹ ni ojuṣe ti ofin fun awọn ijọba ibilẹ bayii.

Aṣofin Ọbasa fẹdun ọkan han si iwa bayii, eleyii ti o n ṣakoba fun atiṣe idokoowo ni irọrun. O ni: “A ni lati ṣe nnkan le e lori. A ni lati jẹ ki wọn mọ pe bi wọn ṣe n daamu awọn idokoowo to bofin mu  to ṣe e ṣe ko tun pese iṣẹ fun awọn ọdọ yii ko bojumu rara, paapaa ti ni bayii ọpọ awọn ọdọ to ti jade ile-ẹkọ ko riṣẹ ṣe. Iru iṣẹ awọn onileeṣẹ kẹkẹ alupupu ifiṣẹran yii yoo ṣadinku iṣẹ lawujọ.

“Awọn ijọba ibilẹ ko ni nnkan ṣe pẹlu pẹlu iforukọsilẹ awọn kẹkẹ alupupu ati awọn kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta. Awọn ijọba ibilẹ ko gbọdo maa gba owo lọwọ awọn kẹkẹ alupupu ifiṣẹran yii, taa ba wo owo kekere ti wọn n gba fun iṣẹ wọn.”

Ile Aṣofin yii wa fẹnu ko pe ki awọn ijọba ibilẹ sọra ṣe pẹlu ojuṣe wọn, ki wọn si ma ṣe lo awọn ọmọ ita lati fi gba owo lọwọ awọn ara ilu mọ.

Ẹwẹ, ninu ipinnu Ile Aṣofin naa, pẹlu aba ti Aṣofin Ganiu Sanni Ọkanlawọn da, pe ki wọn pe ẹka amuṣẹṣe lati paṣẹ fun Alakoso-agba Eto Irinna Ọkọ ni Ipinlẹ Eko ati awọn ajọ ijọba miiran to nii ṣe pẹlu eyi lati ri I daju pe awọn ijọba ibilẹ ko da awọn kẹkẹ alupupu ifiṣẹran laamu mọ lẹnu iṣẹ wọn. Ki Ile-iṣẹ ijọba fun Iroyin ati Ilana Iṣakoso ilu ṣe ilanilọyẹ fun awọn onikẹkẹ alupupu lori ohun gbogbo to yẹ ki wọn ṣe laarin ilu.

Ninu ọrọ rẹ, Aṣofin Bisi Yusuff sọ pe ipinnu yii dara bayii, nitori bi awọn ẹṣọ ijọba ibilẹ yii ṣe n da awọn onikẹkẹ alupupu ifiṣẹran yii laamu ko dara to ni ipinlẹ yii. Ati pe ọpọ igba ni awọn onileeṣẹ ọkọ alupupu yii ti gbe awọn ijọba ibilẹ kan lọ sile ẹjọ lori ọrọ yii, ti wọn si jare wọn.

Aṣiwaju ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju ninu Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Sanai Agunbiade sọ pe iṣẹ awọn onileeṣẹ ifiwe ati ẹru ranṣẹ ti ṣe iranlọwọ fun ọpọ awọn eniyan lati ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu awọn onibaara wọn, o si ti mu igberu ba ọrọ-aje ipinlẹ yii ati ipese iṣẹ fun awọn eniyan. O ṣalaye pe wọn ti ṣe ofin  kan ninu Ile Aṣofin yii to fi pipa owo awọn ijọba ibilẹ soju kan. Ati pe wọn gbọdọ le da ẹnikẹni ti o ba gbowo lọwọ ara-ilu mọ.

Lara awọn aṣofin ti wọn tun fara mọ ifẹnuko yii ni Aṣofin Abiọdun Tọbun, Aṣofin Lukmah Olumoh, Aṣofin Lanre Afini, Aṣofin Moshood Oshun, Aṣofin Jude Idimogu. Aṣofi Setonji David fi mulẹ pe ọpọ awọn risiiti ti awọn ijọba yii maa n ja fun awọn ara ilu fun owo ti wọn ba san lo n jẹ ayederu. Fun idi eyi wọn gbọdọ fopin si dida awọn alupupu ifiṣẹran laamu, nitori wọn n ran ẹka irinna ọkọ ipinlẹ yii lọwọ pẹlu bi wọn ṣe n ba awọn ara ilu fi nnkan ranṣe lọna irọrun yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button